7 Mo ríi tí ó fi ìtara kọlu àgbò náà, ó lu àgbò náà bolẹ̀, ó sì ṣẹ́ ìwo rẹ̀ méjèèjì. Àgbò náà kò sì ní agbára láti dojú kọ ọ́, Òbúkọ náà kàn-án mọ́lẹ̀, ó sì fi ẹsẹ̀ tẹ̀ẹ́ mọ́lẹ̀, kò sì sí ẹni tí ó lè gba àgbò náà là kúrò lọ́wọ́ agbára rẹ̀.
8 Òbúkọ náà sì di alágbára púpọ̀, ṣùgbọ́n nígbà tí ó dé góńgó, agbára rẹ̀ ru sókè, ìwo ńlá a rẹ̀ sì ṣẹ́ dànù, ní ipò o rẹ̀, ìwo mẹ́rin mìíràn hù, ó sì yọrí sí ìhà igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ọ̀run.
9 Lára ọ̀kan nínú un wọn, ìwo mìíràn yọ jáde, ó kékeré, ṣùgbọ́n ó dàgbà nínú agbára sí ìhà gúsù, àti sí ìhà ìlà oòrun àti sí ilẹ̀ dídára.
10 Ó sì dàgbà títí ó fi kan ẹgbẹ́ ogun ọ̀run, ó sì jù lára àwọn ẹgbẹ́ ogun ọ̀run sí ayé ó sì tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀,
11 ó sì gbé ara rẹ̀ ga gẹ́gẹ́ bí ọmọ aládé ẹgbẹ́ ogun ọ̀run; ó sì mú ẹbọ ojoojúmọ́ kúrò lọ́dọ̀ ọ rẹ̀, ó sì gba àyè ibi mímọ́ rẹ̀.
12 A fún-un ní ẹgbẹ́ ogun ọ̀run àti ẹbọ ojojúmọ́ nítorí ìwà ọlọ̀tẹ̀ ẹ rẹ̀: ó sọ òtítọ́ nù nínú gbogbo ohun tó ṣe.
13 Nígbà náà, ni mo gbọ́ tí ẹni mímọ́ ń sọ̀rọ̀, àti ẹni mímọ́ mìíràn sọ̀rọ̀ fún-un pé, “Yóò ti pẹ́ tó tí ìran yìí yóò fi wá sí ìmúsẹ-ìran nípa ẹbọ ojojúmọ́, ìṣọ̀tẹ̀ tí ó ń sọ dahoro, àti mímú kí ibi mímọ́ àti ẹgbẹ́ ogun ọ̀run di ìtẹ̀mọ́lẹ̀?”