Dáníẹ́lì 9:19-25 BMY

19 Olúwa, fetí sílẹ̀! Olúwa, Dáríjìn! Olúwa, gbọ́ kí o sì ṣe é! Nítorí i tìrẹ, Ọlọ́run mi, má ṣe pẹ́ títí, nítorí ìlú rẹ àti àwọn ènìyàn rẹ ń jẹ́ orúkọ mọ́ ọ lára.”

20 Bí mo ṣe ń sọ̀rọ̀, tí mo sì ń gba àdúrà, tí mo ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi àti ẹ̀ṣẹ̀ àwọn Ísírẹ́lì ènìyàn mi, tí mo sì ń mú ẹ̀bẹ̀ mi tọ Olúwa Ọlọ́run mi nítorí òkè mímọ́ rẹ.

21 Bí mo ṣe ń gba àdúrà náà lọ́wọ́, Gébúrẹ́lì ọkùnrin tí mo rí nínú ìran ìṣáájú, yára kánkán wá sí ọ̀dọ̀ mi ní àkókò ẹbọ àṣáálẹ́.

22 Ó jẹ́ kí ó yé mi, ó sì wí fún mi pé, “Dáníẹ́lì, mo wá láti jẹ́ kí o mọ̀ kí o sì ní òye.

23 Bí o ṣe bẹ̀rẹ̀ sí ní gba àdúrà, a fún ọ ní ìdáhùn kan, èyí tí mo wá láti sọ fún ọ, nítorí ìwọ jẹ́ àyànfẹ́ gidigidi. Nítorí náà, gba ọ̀rọ̀ náà yẹ̀wò kí ìran náà sì yé ọ:

24 “Àádọ́rin ọ̀sẹ̀ ni a pàṣẹ fún àwọn ènìyàn rẹ àti fún àwọn ìlú mímọ́ ọ rẹ láti parí ìrékọjá, láti fi òpin sí ẹ̀ṣẹ̀, láti ṣe ètùtù sí ìwà búburú, láti mú òdodo títí ayé wá, láti ṣe èdìdì ìran àti wòlíì àti láti fi òróró yan ẹni mímọ́ jùlọ.

25 “Nítorí náà, mọ èyí pé: Láti ìgbà tí a ti gbé ọ̀rọ̀ náà jáde wí pé kí a tún Jérúsálẹ́mù se, kí a sì tú un kọ́, títí ẹni òróró náà, alákòóso wa yóò fi dé, ó jẹ́ ọ̀ṣẹ̀ méje àti ọ̀sẹ̀ méjìlélọ́gọ́ta a ó sì tún ìgboro àti yàrá rẹ̀ mọ, ṣùgbọ́n ní àkókò wàhálà ni.