14 Wọ́n mú wọn gbé ìgbé ayé kíkorò nípa iṣẹ́ ẹ bíríkì àti àwọn onírúurú iṣẹ́ oko; àwọn ará Éjíbítì ń lò wọ́n ní ìlòkulò.
15 Ọba Éjíbítì sọ fún àwọn agbẹ̀bí Hébérù ti orúkọ wọn ń jẹ́ Ṣífúrà àti Púà pé:
16 “Nígbà ti ẹ̀yin bá ń gbẹ̀bí àwọn obìnrin Hébérù, tí ẹ sì kíyèsí wọn lórí ìkúnlẹ̀ ìrọbí wọn, bí ó bá jẹ́ ọkùnrin ni ọmọ náà, ẹ pa á; ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ obìnrin, ẹ jẹ́ kí ó wà láàyè.”
17 Ṣùgbọ́n àwọn agbẹ̀bí bẹ̀rù Ọlọ́run, wọn kò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ọba Éjíbítì ti wí fún wọn; wọ́n jẹ́ kí àwọn ọmọkùnrin wà láàyè.
18 Ọba Éjíbítì pe àwọn agbẹ̀bí ó sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ṣe èyí?, Èéṣe tí ẹ̀yin fi dá àwọn ọmọkùnrin si?”
19 Àwọn agbẹ̀bí náà sì dá Fáráò lóhùn pé, “Àwọn obìnrin Hébérù kò rí bí àwọn obìnrin Éjíbítì, wọ́n ní agbára, wọ́n sì ti máa ń bí ọmọ kí àwọn agbẹ̀bí tó dé ọ̀dọ̀ wọn.”
20 Nítorí náà Ọlọ́run ṣàánú fún àwọn agbẹ̀bí náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ń le sí i, wọ́n sì ń pọ̀ sí i jọjọ.