1 Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé, “Padà tọ Fáráò lọ kí ó sì sọ fún un pé, ‘Èyí ni Olúwa wí: Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn ó bá à lè sìn mi.
2 Bí ìwọ bá kọ̀ láti jẹ́ kí wọn ó lọ, èmi yóò fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀pọ̀lọ́ kọ lu gbogbo orílẹ̀ èdè rẹ.
3 Odò Náílì yóò kún fún ọ̀pọ̀lọpọ́ àwọn ọ̀pọ̀lọ́. Wọn yóò gókè wá sí ààfin rẹ, àti yàrá rẹ ni orí ìbùsùn rẹ. Wọn yóò gòkè wá sí ilé àwọn ìjòyè rẹ àti sí ara àwọn ènìyàn rẹ, àti sí ibi ìdáná rẹ, àti sí inú ìkòkò ìyẹ̀fun rẹ.
4 Àwọn ọ̀pọ̀lọ́ yóò gun ara rẹ àti ara àwọn ìjòyè rẹ, àti ara gbogbo àwọn ènìyàn rẹ.’ ”
5 Ní ìgbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé, “Sọ fún Árónì, ‘Kí ó na ọwọ́ rẹ̀ jáde pẹ̀lú ọ̀pá sí orí àwọn odò kékèké àti odò ńlá, àti sí orí àwọn àbàtà kí ó sì mú àwọn ọ̀pọ̀lọ́ gòkè wá sí ilẹ̀ Íjíbítí.’ ”
6 Ní ìgbà náà ni Árónì sì na ọwọ́ rẹ̀ jáde sí orí àwọn omi Éjíbítì, àwọn ọ̀pọ̀lọ́ sì wá, wọ́n sì bo gbogbo ilẹ̀.
7 Ṣùgbọ́n àwọn onídan ilẹ̀ Éjíbítì ṣe bákan náà pẹ̀lú agbára òkùnkùn wọn. Àwọn náà mú kí ọ̀pọ̀lọ́ gun wá sí orí ilẹ̀ Éjíbítì.
8 Fáráò ránṣẹ́ pe Mósè àti Árónì, ó sì sọ fún wọn pé, “Gbàdúrà sí Olúwa kí ó mú àwọn ọ̀pọ̀lọ́ wọ̀nyí kúrò lọ́dọ̀ mi àti lára àwọn ènìyàn mi, Èmi yóò sì jẹ́ kí àwọn ènìyàn rẹ kí ó lọ láti rúbọ sí Olúwa.”
9 Mósè sọ fún Fáráò pé, “Jọ̀wọ́ sọ fún mi ìgbà ti èmi yóò gbàdúrà fún ọ àti àwọn ìjòyè rẹ àti fún àwọn ènìyàn rẹ, kí àwọn ọ̀pọ̀lọ́ wọ̀nyí bá lè lọ lọ́dọ̀ rẹ àti ní àwọn ilé yín tí wọn yóò sì wà nínú odò Náílì nìkan.”
10 Fáráò wí pé, “Ni ọ̀lá.”Mósè sì dáhùn pé, “Yóò sì rí bí ìwọ ti sọ, kí ìwọ kí ó lè mọ̀ pé kò sí ẹni bí Olúwa Ọlọ́run wa.
11 Àwọn ọ̀pọ̀lọ́ yóò fi ìwọ àti àwọn ilé yín àti ìjòyè rẹ, àti àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀, wọn yóò sì wà nínú Náìlì nìkan.”
12 Lẹ́yìn tí Mósè àti Árónì tí kúrò ní ìwájú Fáráò, Mósè gbé ohùn ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ sókè sí Olúwa nípa àwọn ọ̀pọ̀lọ́ tí ó ti ran sí Fáráò.
13 Olúwa sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Mósè tí béèrè. Àwọn ọ̀pọ̀lọ́ sì kú nínú ilé àti ní ìta, gbangba àti nínú oko.
14 Wọ́n sì kó wọn jọ ni okíti okíti gbogbo ilẹ̀ sì ń rùn.
15 Ṣùgbọ́n ni ìgbà tí Fáráò rí pé ìtura dé, ó sé ọkàn rẹ̀ le kò sì fetí sí Mósè àti Árónì gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti wí.
16 Olúwa sọ fún Mósè pé, “Sọ fún Árónì, ‘Na ọ̀pá rẹ jáde kí ó sì lu eruku ilẹ̀,’ jákè jádò gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì ni erùpẹ̀ ilẹ̀ yóò ti di kòkòrò-kantíkantí.” (Kòkòrò kan tí ó ní ìyẹ́ méjì tí ó sì ń ta ni)
17 Wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀, Nígbà tí Árónì na ọwọ́ rẹ́ jáde pẹ̀lú ọ̀pá ní ọwọ́ rẹ̀, tí ó sì lu eruku ilẹ̀, kòkòrò-kantíkantí sì wà lára àwọn ènìyàn àti àwọn ẹranko wọn. Gbogbo eruku jákè-jádò ilẹ̀ Éjíbítì ni ó di kòkòrò-kantíkantí.
18 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn onídán gbìdánwò láti da kòkòrò-kantíkantí pẹ̀lú agbára òkùnkùn wọn, wọn kò le è ṣé. Kòkòrò-kantíkantí sì wà lára àwọn ẹranko wọn.
19 Àwọn onídán sì sọ fún Fáráò pé, “Ìka Ọlọ́run ni èyí.” Ṣùgbọ́n àyà Fáráò sì yigbì, kò sì fetí sílẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ.
20 Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé, “Lọ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù kí o sì ko Fáráò lójú bí ó ṣe ń lọ sí odò, kí o sì sọ fún un pé, ‘Èyí ni Olúwa sọ: Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn kí ó bá à lè sìn mi.
21 Bí ìwọ kò bá jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, èmi yóò rán ọ̀pọ̀lọpọ̀ eṣinṣin sí ara rẹ àti sí ara àwọn ìjòyè rẹ, àti sí ara àwọn ènìyàn rẹ̀, sí àwọn ilẹ̀ rẹ̀. Gbogbo ilé àwọn ará Éjíbítì ni yóò kún fún eṣinṣin àti orí ilẹ̀ tí wọ́n wà pẹ̀lú.
22 “ ‘Ṣùgbọ́n ni ọjọ́ náà, èmi yóò ya ilẹ̀ Góṣénì sọ́tọ̀, níbi tí àwọn ènìyàn mi ń gbé, ọ̀wọ́ eṣinṣin kankan ki yóò dé ibẹ̀. Kí ìwọ kí ó lè mọ̀ pé, èmi ni Olúwa, mo wà ni ilẹ̀ yìí.
23 Èmi yóò pààlà sáàárin àwọn ènìyàn mi àti àwọn ènìyàn rẹ. Àwọn iṣẹ́ ìyanu yìí yóò ṣẹlẹ̀ ni ọ̀la.’ ”
24 Olúwa sì ṣe èyí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ eṣinṣin sì ya wọ ààfin Fáráò àti sí ilé àwọn ìjòyè rẹ̀. Gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì bàjẹ́ pẹ̀lú ọ̀wọ́ eṣinṣin wọ̀n-ọn-nì.
25 Nígbà náà ni Fáráò ránṣẹ́ pe Mósè àti Árónì, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa lọ kí ẹ sì rúbọ sí Ọlọ́run yín ní ilẹ̀ yìí.”
26 Ṣùgbọ́n Mósè sọ pé, “Èyí ló tọ́, ẹbọ tí a ó rú sí Olúwa Ọlọ́run wa yóò jẹ́ ohun ìríra sí àwọn ará ilẹ̀ Éjíbítì. Bí a bá ṣe ìrúbọ ti yóò jẹ́ ìríra ni ojú wọn ṣé wọn kò ní sọ òkúta lù wá?
27 A gbọdọ̀ lọ ni ìrìn ọjọ́ mẹ́ta sí inú ihà láti rúbọ sí Olúwa Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ó ti pàṣẹ fún wa.”
28 Nígbà náà ni Fáráò wí pé, “Èmi yóò jẹ́ ki ẹ lọ rúbọ sí Olúwa Ọlọ́run yín nínú ihà, ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ rìn jìnnà jù. Ẹ gbàdúrà fún mi.”
29 Mósè dáhùn ó wí pé, “Bí èmi bá ti kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ, èmi yóò gbàdúrà sí Olúwa, awọn esinsin yóò fi Fáráò, àwọn ìjòyè rẹ, àti àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀ ní ọ̀la ṣùgbọ́n ǹjẹ́ ìdánílójú wa pé Fáráò kò tún ni lo ẹ̀tàn láti má jẹ́ kí àwọn ènìyàn kí ó lọ rú ẹbọ sí Olúwa.”
30 Nígbà náà ni Mósè kúrò ni ọ̀dọ̀ Fáráò, ó sì gbàdúrà sí Olúwa;
31 Olúwa sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Mósè ti béèrè: Àwọn esinsin kúrò lára Fáráò àti àwọn ìjòyè rẹ̀ àti lára àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú, esinsin kan kò sì sẹ́kù.
32 Ṣùgbọ́n ni àkókò yìí náà, Fáráò sé ọkàn rẹ le kò sì jẹ́ kí àwọn ènìyàn ó lọ.