Ékísódù 25 BMY

Ọrẹ-Ẹbọ Fún Àgọ́

1 Olúwa sì wí fún Mósè pé,

2 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kí wọn mú ọrẹ wá fún mi ìwọ yóò gba ọrẹ náà fún mi ni ọwọ́ ọkùnrin kọ̀ọ̀kan ti ọkàn rẹ bá fẹ́ láti fi fún mi.

3 Wọ̀nyí ni ọrẹ ti ìwọ yóò gbà ni ọwọ́ ọ wọn: wúrà, fàdákà, idẹ,

4 aṣọ aláwọ̀ aró, aṣọ aláwọ̀ aró-fẹ́ẹ́rẹ́, aṣọ aláwọ̀ òdòdó, aṣọ funfun-láú, ìrun ewúrẹ́.

5 Awọ àgbò tí a rẹ ní pupa àti awọ ewúrẹ́-dò; igi kásíà;

6 Òróró olífì fún iná títàn, òróró olóórùn dídùn fún ìtasórí àti fún tùràrí olóórùn dídùn,

7 àti òkúta oníkì àti òkúta olówó iyebíye ti a fi ṣe ọ̀ṣọ́ sí ara ẹ̀wù éfódi àti ẹ̀wù ìgbàyà.

8 “Nígbà náà ni ìwọ yóò jẹ́ kí wọn kọ́ ibi mímọ́ fún mi. Èmi yóò sì máa gbé ní àárin wọn.

9 Gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí ti mo fi hàn ọ́, nípa àpẹẹrẹ àgọ́, àti àpẹẹrẹ gbogbo ohun èlò inú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó sì ṣe é.

Àpótí Ẹ̀rí

10 “Kí wọn kí ó fi igi kasíà ṣe àpótí, kí gígùn rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì àti ààbọ̀, kí fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀.

11 Bo orí rẹ̀ pẹ̀lú ojúlówó wúrà, bò ó ni inú àti ìta kí o sì fi wúrà gbá etí rẹ̀ yíká.

12 Ṣe òrùka wúrà mẹ́rin fún un. Kí o sì so wọ́n mọ́ ẹṣẹ̀ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, òrùka wúrà méjì yóò wà ní ẹ̀gbẹ́ kìn-ín-ní, òrùka wúrà méjì yóò wà ní ẹgbẹ́ kejì.

13 Fi igi kaṣíà ṣe òpó mẹ́rin, kí o sì fi wúrà bò ó.

14 Fi òpó náà bọ òrùka ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan àpótí náà láti fi gbé e.

15 Òpó náà yóò wá nínú òrùka lára àpótí ẹ̀rí; a ko ní yọ wọ́n kúrò.

16 Nígbà náà ni ìwọ yóò fi ẹ̀rí ti èmi yóò fi fún ọ sínú àpótí náà.

17 “Ojúlówó wúrà ni kí o fi se ìtẹ́ àánú; ìgbọ̀nwọ́ méjì àti ààbọ̀ ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀ ní fífẹ̀.

18 Fi wúrà tí a lù se kérúbù méjì sí igun ìtẹ́-àánú.

19 Ṣe kérúbù kan sí igun kìn-ín-ní àti kérúbù kejì sí igun kejì kí kérúbù náà jẹ́ irú kan náà ní igun méjèèjì.

20 Apá àwọn kérúbù náà yóò wà ní gbígbé sókè, tí wọn yóò sì fi apá wọn se ibòòji sí orí ìtẹ́ àánú. Àwọn kérúbù náà yóò kọ ojú sí ara wọn, wọn yóò máa wo ọ̀kánkán ìtẹ́.

21 Gbé ọmọrí orí àpótí ẹ̀rí kí o sì fi ẹ̀rí èyí tí èmí yóò fi fún ọ sínú àpótí ẹ̀rí.

22 Níbẹ̀, ni òkè ìtẹ́, ní àárin kérúbù méjèèjì ti ó wà ni orí àpótí ẹ̀rí ni èmi yóò ti pàdé rẹ, ti èmi yóò sì fún ọ ní àwọn òfin mi fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.

Tábìlì

23 “Fi igi kaṣíà kan tábílì: ìgbọ̀nwọ́ méjì ní gígùn ìgbọ̀nwọ́ kan ní fífẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀ ní gíga.

24 Kí o fi ojúlówó wúrà bò ó, kí o sì mọ wúrà yíká.

25 Bákan náà, mọ etí rẹ̀ yíká pẹ̀lú wúrà níwọ̀n fífẹ ìbúwọ́, kí o sì fi wúrà mímọ́ sí ibí orúka rẹ.

26 Ṣe òrùka wúrà mẹ́rin fún tábìlì náà, kí o so ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn mọ́ igun ẹsẹ̀ rẹ̀ kọ̀ọ̀kan.

27 Òrùka náà ko gbọdọ̀ jìnnà sí etí rẹ̀, kí ó lè gbá òpó mú nígbà tí a bá ń gbé tábìlì náà.

28 Fi igi kaṣíà ṣe òpó, fi wúrà bò wọ́n, kí o sì máa fi wọ́n gbé tábìlì náà.

29 Fi ojúlówó wúrà se àwo àti ṣíbí rẹ̀, kí o sì ṣe àwokòtò àti ago pẹ̀lú fún dída ọrẹ jáde.

30 Gbé àkàrà ìfihàn sí orí tabílì yìí, kí ó le wà ní iwájú mi ni gbogbo ìgbà.

Ọ̀pá Fítílà.

31 “Mú ojúlówó wúrà, lù ú dáradára, kí o sì fi ṣe ọ̀pá fìtílà, ìsàlẹ̀ àti apá rẹ̀, kọ́ọ̀bù rẹ̀ ti ó dàbí òdòdó, ìṣọ àti ìtànná rẹ̀ yóò jẹ́ ara kan náà pẹ̀lú rẹ̀.

32 Ẹ̀ka mẹ́fà ni yóò yọ ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀pá fìtílà: mẹ́ta ní ẹ̀gbẹ́ kìn-ín-ní mẹ́ta ni ẹ̀gbẹ́ kejì.

33 Kọ́ọ̀bù mẹ́ta tí a se bí òdòdó alímọ́ńdì tí ó sọ tí ó sì tanná ni yóò wà ni apá kan, mẹ́ta yóò sì wà ní apá kejì, àti bẹ́ẹ̀ fún àwọn ẹ̀ka mẹ́fẹ̀ẹ̀fà tí ó jáde lára ọ̀pá fìtílà.

34 Ní ara ọ̀pá fìtílà ni kọ́ọ̀bù mẹ́rin ti a se gẹ́gẹ́ bí òdòdó alímọńdì ti ó ni ìṣọ àti ìtànná yóò wà.

35 Ìṣọ kan yóò wà lábẹ́ méjì àkọ́kọ́ tí ó yọ lára ọ̀pá fìtílà, ìṣọ kejì lábẹ́ ẹ̀ka méjì kejì, ìṣọ kẹta ní abẹ́ ẹ̀ka mẹ́ta kẹta: ẹ̀ka mẹ́fà ní àpapọ̀.

36 Ìṣọ àti ẹ̀ka yóò di ara kan náà pẹ̀lú òpó fìtílà ti a fi ojúlówó wúrà ti a lù ṣe.

37 “Nígbà náà ni ìwọ yóò se fítílà méje. Ìwọ yóò sì gbe ka orí rẹ̀, kí wọn bá a lè tan iná sí iwájú rẹ̀.

38 Ike ọ̀pá àbẹ́là àti ọpọ́n agogo gbọdọ̀ jẹ́ èyí tí a fi ojúlówó wúrà ṣe.

39 Ìwọ̀n ojúlówó wúrà ti ó tó talẹ́ǹtì kan ni a gbọdọ̀ fi se ọ̀pá fìtílà àti àwọn ti ó so mọ́ ọn.

40 Rí i pé ó ṣe gẹ́gẹ́ bí bátànì ti mo fihàn ọ́ ni orí òkè.