Ékísódù 28 BMY

Aṣọ Àlùfáà.

1 “Ìwọ sì mú Árónì arákùnrin rẹ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, mú un kúrò ni àárin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ Nádáhù, Ábíhù, Élíásárì, àti Ítamárì, kí wọn kí ó lè sìn mí gẹ́gẹ́ bí àlùfáà.

2 Ìwọ yóò sì dá aṣọ mímọ́ fún Árónì arákùnrin rẹ, láti fún un ni ọ̀ṣọ́ àti ọlá.

3 Ìwọ yóò sì sọ fún gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn, àwọn ẹni tí mo fún ní ọgbọ́n, kí wọn kí ó lè dá aṣọ fún Árónì, fún ìyà-sí-mímọ́ rẹ̀, kí ó lè ba à sìn mí gẹ́gẹ́ bí àlùfáà.

4 Wọ̀nyí ni àwọn aṣọ tí wọn yóò dá: ìgbàyà kan, ẹ̀wù èfòdì, ọ̀já àmùrè kan, ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ ọlọ́nà, fìlà àti aṣọ ìgúnwà. Kí wọn kí ó dá àwọn aṣọ mímọ́ yìí fún Árónì arákùnrin rẹ àti àwọn ọmọ rẹ̀, kí wọn kí ó lè sìn mí gẹ́gẹ́ bí àlùfáà.

5 Wọn yóò sì lo wúrà, aṣọ aláró, elésèé àlùkò àti ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ dáradára.

Ẹ̀wù èfòdì

6 “Wọn yóò sì dá ẹ̀wù èfòdì ti wúrà, tí aṣọ aláró, elésèé àlùkò àti ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókún wíwẹ́ iṣẹ́ ọlọ́nà.

7 Kí ó ni aṣọ èjìká méjì tí a so mọ́ igun rẹ̀ méjèèjì, kí a lè so ó pọ̀.

8 Àti onírúurú ọnà ọ̀já rẹ̀, tí ó wà ni orí rẹ̀, yóò rí bákan náà, gẹ́gẹ́ bi iṣẹ́ rẹ̀, tí wúrà, ti aṣọ aláró, òdòdó àti ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́.

9 “Ìwọ yóò sì mú òkúta óníkísì méjì, ìwọ yóò sì fún orúkọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sára wọn.

10 Ní ti ìbí wọn, orúkọ àwọn mẹ́fà sára òkúta kan àti orúkọ àwọn mẹ́fà tókù sára òkúta kejì.

11 Iṣẹ́ ọnà òkúta fínfín, bí ìfín èdìdì àmì, ni ìwọ yóò fún òkúta méjèèjì gẹ́gẹ́ bí orúkọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì: ìwọ yóò sì dè wọ́n sí ojú ìdè wúrà.

12 Ìwọ yóò sì so wọ́n pọ̀ mọ́ èjìká èfòdì náà ní òkúta ìràntí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Árónì yóò sì máa ní orúkọ wọn ní wájú Olúwa ní èjìká rẹ̀ méjèèjì fún ìrántí.

13 Ìwọ yóò sì ṣe ojú ìdè wúrà

14 Àti okùn ẹ̀wọ̀n méjì ti kìkì wúrà, gẹ́gẹ́ bí ọ̀já àmùrè kí o sì so ẹ̀wọ̀n náà mọ́ ojú ìdè náà.

Ìgbàyà

15 “Ìwọ yóò fi iṣẹ́ ọgbọ́n ṣe ìgbàyà fún ìpinu iṣẹ́ ọnà gbẹ́nàgbẹ́nà. Ìwọ yóò ṣe é bí ẹ̀wù èfòdì ti wúrà, ti aṣọ aláró, ti elésèé àlùkò, ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́ dáradára.

16 Kí ìhà mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ se déédé—kí ó jẹ́ ìwọ̀n ṣẹ́ńtímítà méjìlélógún ní gíga àti ìwọ̀n ṣẹ̀ńtímítà méjìlélógun (22 centimeters) ní fífẹ̀ kí o sì ṣe é ní ìsẹ́po méjì.

17 Nígbà náà ni ìwọ yóò de òkúta iyebíye mẹ́rin sára ẹṣẹ̀ rẹ̀. Ní ẹṣẹ̀ àkọ́kọ́ ni kí rúbì, tópásì àti bérílì wà;

18 ní ẹṣẹ̀ kejì émérálídì, sáfírù, àti díámóńdì;

19 ní ẹṣẹ̀ kẹta, lígúrè, ágátè, àti ámétísítì;

20 ní ẹṣẹ̀ kẹrin, bérílù, àti óníkísì àti Jásípérì. A ó sì tò wọ́n sí ojú wúrà ní dìde wọn.

21 Òkúta méjìlá (12) yóò wà, ọ̀kọ̀ọ̀kan fún orúkọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì olúkúlùkù èdìdì àmì pẹ̀lú orúkọ ẹnìkọ̀ọ̀kan bí ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá.

22 “Fún ìgbàyà náà, ìwọ yóò se okùn ẹ̀wọ̀n ti kìkì wúrà, gẹ́gẹ́ bí ọ̀já àmùrè.

23 Ìwọ yóò ṣe òrùka wúrà méjì fún un, kí o sì so wọ́n mọ́ igun igbá àyà méjèèjì.

24 Ìwọ yóò so ẹ̀wọ̀n wúrà méjèèjì mọ́ òrùka ní igun ìgbàyà náà,

25 àti eti ẹ̀wọ̀n méje ni kí o so mọ́ ojú ìdè méjèèjì, kí o sì fi sí èjìká ẹ̀wù éfódì náà níwájú.

26 Ìwọ yóò ṣe òrùka wúrà méjì, ìwọ yóò sì so wọ́n mọ́ igun méjì igbáàyà kejì ní ìhà inú tí ó ti ẹ̀wù éfódì náà.

27 Ìwọ yóò sì se orùkọ wúrà méjì, ìwọ yóò sì fi wọ́n sí èjìká ẹ̀wù ẹ́fó dì méjèèjì ní ìṣẹ̀lẹ̀, sí ìhà iwájú rẹ̀, tí ó kọ́jú sí ìṣẹ̀lú rẹ̀, lókè onírúurú ọnà ọ̀já ẹ̀wù éfódì náà.

28 Wọn yóò sì so òrùka ìgbàyà mọ́ òrùka ẹ̀wù èfòdì pẹ̀lú ọ̀já aláró, pa á pọ̀ mọ́ ìgbànú, kí a má ba à tú ìgbàyà náà kúrò lára ẹ̀wù èfòdì náà.

29 “Nígbà kúgbà tí Árónì bá wọ ibi mímọ́, òun yóò ru orúkọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì (Ẹ̀yà méjìlá) ní gbogbo ọ̀kan rẹ̀ ni ìgbàyà ìpinu bí ìrántí nígbà gbogbo níwájú Olúwa.

30 Bákan náà ìwọ yóò sì mu Úrímù àti Tímímù sínú ìgbàyà, kí wọn kí ó wà ní ọkàn Árónì nígbàkúgbà tí ó bá ń wólẹ̀ níwájú Olúwa. Árónì yóò sì máa ru ohun ti a ń fi se ìpinu fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ọkàn rẹ̀ nígbàgbogbo níwájú Olúwa.

Àwọn Aṣọ Àlùfáà Mìíràn.

31 “Ìwọ yóò sìṣe aṣọ ìgúnwà ẹ̀wù éfódì náà ní kìkì aṣọ aláró,

32 pẹ̀lú ojú ọrùn kí ó wà láàrin rẹ̀ fún orí. Kí iṣẹ́ ọ̀nà wà létí rẹ̀ bí ìsẹ́tí yí i ká bí agbádá, kí ó má ba à ya.

33 Ṣe pómégánátè ti aṣọ aláró, ti elésèé àlùkò àti ti òdòdó yí ìsẹ́ti ọ̀já àmùrè náà ká, pẹ̀lú aago wúrà láàrin wọn.

34 Àwọn aago wúrà àti àwọn pómégánátè ni kí ó yí ìsẹ́tí ọ̀já àmùrè náà ká.

35 Árónì gbọdọ̀ máa wọ̀ ọ́ nígbà tí o bá ń sisẹ́. A ó sì máa gbọ́ ìró àwọn agogo nígbà tí ó bá ń wọ ibi mímọ́ níwájú Olúwa àti nígbà tí ó bá ń jáde bọ̀, kí ó má ba à kú.

36 “Ìwọ yóò sì ṣe àwo kìkì wúrà, ìwọ yóò sì fín sára rẹ̀ bí, fífín èdìdì àmì pé: ‘Mímọ́ sí Olúwa.’

37 Ìwọ yóò fi ọ̀já aláró sára rẹ̀ ìwọ yóò sì so ó mọ́ fìlà náà; kí ó sì wà níwájú fìlà náà.

38 Kí ó wà níwájú orí Árónì, kí ó sì lè máa ru ẹ̀bi tí ó jẹ mọ́ ẹ̀bùn mímọ́ ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti yà sí mímọ́, èyíkéyìí tí ẹ̀bùn wọn lè jẹ́. Yóò máa wà níwájú orí Árónì nígbà gbogbo, kí wọn lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa.

39 “Ìwọ yóò sì fi ọ̀gbọ̀ dáradára hun ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀, ìwọ yóò sì fi ọ̀gbọ̀ dáradára ṣe fìlà. Iwọ yóò sì fi ṣẹ́ abẹ́rẹ́ ṣe ọ̀já àmùrè.

40 Ìwọ yóò sì dá ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀, ọ̀já àmùrè àti ìgbàrí fún àwọn ọmọ Árónì, láti fún wọn ní ọ̀ṣọ́ àti ọlá.

41 Lẹ́yìn tí ìwọ ti fi àwọn aṣọ wọ̀nyí wọ Árónì arákùnrin rẹ, ìwọ yóò sì fi wọ àwọn ọmọ rẹ̀ pẹlú, ìwọ óta òróró sí wọn ní orí, ìwọ yóò sì ya wọ́n sí mímọ́. Ìwọ yóò sì Sọ wọ́n di mímọ́, kí wọn kí o lè máa se iṣe àlùfáà.

42 “Ìwọ yóò dá aṣọ àwòtẹ́lẹ̀ fún wọn, kí wọn lè máa fi bo ara wọn, kí ó dé ìbàdí dé itan.

43 Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ gbọdọ̀ wọ̀ wọ́n nígbàkugbà tí wọ́n bá wọ àgọ́ àjọ lọ tàbí nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ pẹpẹ láti ṣiṣẹ́ ní ibi mímọ́ kí wọn kí ó má ba à dẹ́sẹ̀, wọn a sì kú.“Èyí jẹ́ ìlànà láéláé fún Árónì àti fún irú ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀.