1 Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé, “Wò ó, èmi ti ṣe ọ bí Ọlọ́run fún Fáráò, Árónì arákùnrin rẹ ni yóò jẹ́ wòlíì (agbẹnusọ) rẹ.
2 Ìwọ yóò sì sọ ohun gbogbo tí èmi ti pàṣẹ fún ọ, Árónì arákùnrin rẹ yóò sí sọ fún Fáráò kí ó jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ni ilẹ̀ rẹ̀.
3 Ṣùgbọ́n èmi yóò ṣé Fáráò lọ́kàn le. Bí mo tilẹ̀ ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àmì àti ìyanu ni Éjíbítì,
4 ṣíbẹ̀ òun kì yóò fi etí sí ọ. Nígbà náà ni èmi yóò gbé ọwọ́ mi lé Éjíbítì, pẹ̀lú agbára ìdájọ́ ńlá mi ni èmi yóò mú àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì jáde ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́.
5 Àwọn ará Éjíbítì yóò sì mọ̀ pé èmi ni Olúwa ní ìgbà tí mo bá na ọwọ́ mi jáde lé Éjíbítì, tí mo sì mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò níbẹ̀.”
6 Mósè àti Árónì sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ́ fún wọn.
7 Mósè jẹ́ ọmọ ọgọ́rin ọdún (80) Árónì sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́talélọ́gọ́rin (83) ni ìgbà tí wọ́n bá Fáráò sọ̀rọ̀.
8 Olúwa sọ fún Mósè àti Árónì,
9 “Ní ìgbà tí Fáráò bá sọ fún un yín pé, ‘Ẹ ṣe iṣẹ́ ìyanu kan,’ sọ fún Árónì ní ìgbà náà pé, ‘Mú ọ̀pá rẹ kí ó sì sọ ọ́ sílẹ̀ níwájú Fáráò,’ yóò sì di ejò.”
10 Nígbà náà ni Mósè àti Árónì tọ Fáráò lọ, wọ́n sì ṣe bí Olúwa ti pàṣẹ fún wọn, Árónì ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀ ní ìwájú Fáráò àti àwọn ìjòyè rẹ̀, ọ̀pá náà sì di ejò.
11 Fáráò sì pe àwọn amòye, àwọn osó àti àwọn onídán ilẹ̀ Éjíbítì jọ, wọ́n sì fi idán wọn ṣe ohun tí Mósè àti Árónì ṣe.
12 Ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn sọ ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀, ọ̀pá náà sì di ejò. Ṣùgbọ́n ọ̀pá Árónì gbé ọ̀pá tiwọn mì.
13 Ṣíbẹ̀ ọkàn Fáráò sì yigbì, kò si fetí sí wọn gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ.
14 Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé, “Ọkàn Fáráò ti di líle, ó kọ̀ láti jẹ́ kí àwọn ènìyàn náà ó lọ.
15 Tọ Fáráò lọ ni òwúrọ̀ kùtùkùtù bí ó ti ń lọ sí etí odò, dúró ni etí bèbè odò Náílì láti pàdé rẹ, mú ọ̀pá rẹ tí ó di ejò ni ọwọ́ rẹ.
16 Sọ fún un pé, ‘Olúwa Ọlọ́run àwọn Hébérù rán mi sí ọ láti sọ fún ọ pé: Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn kí ó lè sìn mi ni ihà. Ṣùgbọ́n títí di àkókò yìí, ìwọ kò gba.
17 Èyí ni Olúwa wí: Nípa èyí ni ìwọ yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa. Wò ó, èmi yóò fi ọ̀pá ti ó wà ní ọwọ́ mi, èmi yóò ná omi tí ó wà nínú odò Náìlì yóò sì di ẹ̀jẹ̀.
18 Àwọn ẹja tí ó wà nínú odò Náìlì yóò kú, odò náà yóò sì máa rùn, àwọn ará Éjíbítì kò sì ni lè mu omi rẹ̀.’ ”
19 Olúwa sọ fún Mósè, “Sọ fún Árónì, ‘Mú ọ̀pá rẹ kí ó sì na ọwọ́ rẹ jáde lórí àwọn omi Éjíbítì: Lórí àwọn odò kéékèèke àti odò ńlá, lórí àbàtà àti adágún omi;’ wọn yóò sì di ẹ̀jẹ̀. Ẹ̀jẹ̀ yóò wà ni ibi gbogbo ni Éjíbítì, àní nínú ọpọ́n àti nínú kete omi àti nínú ìkòkò tí a pọn omi sí nínú ilé.”
20 Mósè àti Árónì sí ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún wọn. Ó gbé ọ̀pá rẹ̀ sókè ni ìwájú Fáráò àti àwọn ìjòyè rẹ̀, ó sì lu omi odò Náìlì, omi odò náà sì yípadà sí ẹ̀jẹ̀.
21 Ẹja inú odò Náìlì sì kú, odò náà ń rùn gidigidi tí ó fi jẹ́ pé àwọn ará Éjíbítì kò le è mu omi inú rẹ̀. Ẹ̀jẹ̀ sì wà ni ibi gbogbo ni ilẹ̀ Éjíbítì.
22 Ṣùgbọ́n àwọn apidán ilẹ̀ Éjíbítì sì ṣe bákan náà pẹ̀lú agbára òkùnkùn wọn, ọkàn Fáráò sì yigbì ṣíbẹ̀ kò sì fetí sí wọn gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ.
23 Dípò bẹ́ẹ̀, ó yíjú padà, ó sì lọ sí ààfin rẹ̀, kò sì jẹ́ kí àwọn nǹkan wọ̀nyí wà ni oókan àyà rẹ̀.
24 Nígbà náà ni gbogbo àwọn ará Éjíbítì bẹ̀rẹ̀ sí í gbẹ́ etí odò Náílì láti wá omi tí wọn yóò mu, nítorí wọn kò le è mu omi tí ó wà nínú odò náà.
25 Ọjọ́ Méje sì kọjá ti Olúwa ti lu Odò Náílì