18 Ọba Éjíbítì pe àwọn agbẹ̀bí ó sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ṣe èyí?, Èéṣe tí ẹ̀yin fi dá àwọn ọmọkùnrin si?”
19 Àwọn agbẹ̀bí náà sì dá Fáráò lóhùn pé, “Àwọn obìnrin Hébérù kò rí bí àwọn obìnrin Éjíbítì, wọ́n ní agbára, wọ́n sì ti máa ń bí ọmọ kí àwọn agbẹ̀bí tó dé ọ̀dọ̀ wọn.”
20 Nítorí náà Ọlọ́run ṣàánú fún àwọn agbẹ̀bí náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ń le sí i, wọ́n sì ń pọ̀ sí i jọjọ.
21 Nítorí pé àwọn agbẹ̀bí bẹ̀rù Ọlọ́run, Ọlọ́run sì fún wọn ni ìdílé ti wọn.
22 Nígbà náà ni Fáráò pàṣẹ yìí fún gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ pé; “Gbogbo ọmọkùnrin tí a bí ni kí ẹ gbé jù sínú odò Náílì, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ọmọbìnrin ni kí ẹ jẹ́ kí wọn ó wà láàyè.”