8 Nígbà náà ni ọba túntún ti kò mọ nípa Jósẹ́fù jẹ ní ilẹ̀ Éjíbítì.
9 Ó sọ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ “Ẹ wò ó, àwọn ará Ísírẹ́lì ti pọ̀ ní iye àti agbára jù fún wa.
10 Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a lo ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí láti dá wọn lẹ́kun, bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ wọn yóò túbọ̀ máa pọ̀ sí i. Bí ogun bá sì bẹ́ sílẹ̀, wọn yóò darapọ̀ mọ́ àwọn ọ̀tá wa, wọn yóò sì da ojú ìjà kọ wá, wọn yóò sì sá àsálà kúrò ní ilẹ̀ yìí.”
11 Nítorí náà, wọ́n yan àwọn ọ̀gá akóniṣiṣẹ́ lé wọn lórí láti máa ni wọ́n lára pẹ̀lú iṣẹ́ àṣekára. Wọ́n sì kọ́ Pítómi àti Ráméṣéṣì gẹ́gẹ́ bí ìlú ìkó ìṣúra pamọ́ sí fún Fáráò.
12 Ṣùgbọ́n bí a ti ń ni wọ́n lára tó, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń pọ̀ sí i, ti wọn sì ń tàn kálẹ̀; Nítorí náà, àwọn ará Éjíbítì bẹ̀rù nítorí àwọn ará Ísírẹ́lì.
13 Wọ́n sì mú wọn ṣiṣẹ́ àṣekú láìkáánú wọn.
14 Wọ́n mú wọn gbé ìgbé ayé kíkorò nípa iṣẹ́ ẹ bíríkì àti àwọn onírúurú iṣẹ́ oko; àwọn ará Éjíbítì ń lò wọ́n ní ìlòkulò.