6 Igbe ẹkún ńlá yóò sọ jákèjádò gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì. Irú ohun búburú tí kò sẹlẹ̀ rí tí kò sí tún ni sẹlẹ̀ mọ́.
7 Ṣùgbọ́n láàrin àwọn ará Ísírẹ́lì ajá lásán kò ní gbó àwọn ènìyàn tàbí àwọn ẹran wọn.’ Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé Olúwa ti fi ìyàtọ̀ sáàrín àwọn ará Éjíbítì àti Ísírẹ́lì.
8 Gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀ wọ̀nyí yóò tọ̀ mí wá, wọn yóò wólẹ̀ ni iwájú, mi wọn yóò sì máa wí pé, ‘Lọ àti àwọn ènìyàn tí ó tẹ̀ lé ọ!’ Lẹ́yìn náà èmi yóò jáde.” Nígbà náà ni Mósè fi ìbínú jáde kúrò ní iwájú Fáráò
9 Olúwa ti sọ fún Mósè pé, “Fáráò yóò kọ̀ láti fetí sílẹ̀ sí ọ kí iṣẹ́ ìyanu mí le pọ̀ sí ní Éjíbítì.”
10 Mósè àti Árónì ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí níwájú Fáráò, ṣùgbọ́n Olúwa sé ọkàn Fáráò le, òun kò sí jẹ́ kí àwọn Ísírẹ́lì jáde kúrò ni orílẹ̀ èdè rẹ̀.