19 Mósè kó egungun Jósẹ́fù pẹ̀lú rẹ̀ nítorí Jósẹ́fù tí mú kí àwọn ọmọ Isírẹ́lì búra. Ó ti wí pé, “Dájúdájú Ọlọ́run yóò dìde fún ìrànlọ́wọ́ yín ẹ sì gbọdọ̀ kó egungun mi lọ pẹ̀lú yín kúrò níhìnín yìí.”
20 Wọ́n sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n láti Súkótì lọ, wọ́n sì pàgọ́ sí Ẹ́tamù ní etí ihà.
21 Olúwa sì ń lọ níwájú wọn, nínú òpó ìkùùkuu ní ọ̀san láti máa ṣe amọ̀nà wọn àti ní òru nínú òpó iná láti máa tan ìmọ́lẹ̀ fún wọn, kí wọn lè máa lọ nínú ìrìnàjò wọn ní tọ̀sán tòru.
22 Ìkùùku náà kò kúrò ní ààyè rẹ̀ ní ọ̀sán, bẹ́ẹ̀ ni, òpó iná kò kúrò ní ààyè rẹ̀ ni òru, ní iwájú àwọn ènìyàn náà.