11 “Ta ni nínú àwọn òrìṣà tó dàbí rẹ, Olúwa?Ta ló dàbí rẹ:ní títóbi,ní mímọ́ Ẹlẹ́rù ni yìnTí ń se ohun ìyanu?
12 Ìwọ na apá ọ̀tún rẹIlẹ̀ si gbé wọn mì.
13 “Nínú ìfẹ́ rẹ ti kì í ṣákìíìwọ se amọ̀nàÀwọn ènìyàn náà tí ìwọ ti ràpadàNínú agbára rẹ ìwọ yóò tọ́ wọn lọsí ibi ìjókòó rẹ mímọ́.
14 Orílẹ̀-èdè yóò gbọ́ wọn yóò wárìrìÌkáàánú yóò mi àwọn ènìyàn palẹ́sítínì.
15 Ìbẹ̀rù yóò mú àwọn ìjòyè Édómù,Àwọn olórí Móábù yóò wárìrìÀwọn ènìyàn Kénánì yóò sì yọ̀ danu;
16 Ìbẹ̀rù-bojo yóò subú lù wọ́n nítorínína títóbi apá rẹ̀wọn yóò dúró jẹ́ ẹ́ láì mira bí i òkútaTítí àwọn ènìyàn rẹ yóò fi ré kọjá, Olúwa,Títí tí àwọn ènìyàn tí o ti rà yóò fi ré kọjá.
17 Ìwọ yóò mú wọn wá láti gbìn wọ́nni ori òkè ti ìwọ jogún;Ní ibi ti ìwọ ṣe fún ara rẹ, Olúwa.Láti máa gbé ibi mímọ́ ti ìwọ fi ọwọ́ rẹ gbékalẹ̀, Olúwa.