15 Ìbẹ̀rù yóò mú àwọn ìjòyè Édómù,Àwọn olórí Móábù yóò wárìrìÀwọn ènìyàn Kénánì yóò sì yọ̀ danu;
16 Ìbẹ̀rù-bojo yóò subú lù wọ́n nítorínína títóbi apá rẹ̀wọn yóò dúró jẹ́ ẹ́ láì mira bí i òkútaTítí àwọn ènìyàn rẹ yóò fi ré kọjá, Olúwa,Títí tí àwọn ènìyàn tí o ti rà yóò fi ré kọjá.
17 Ìwọ yóò mú wọn wá láti gbìn wọ́nni ori òkè ti ìwọ jogún;Ní ibi ti ìwọ ṣe fún ara rẹ, Olúwa.Láti máa gbé ibi mímọ́ ti ìwọ fi ọwọ́ rẹ gbékalẹ̀, Olúwa.
18 Olúwa yóò jọbaláé àti láéláé.”
19 Nígbà ti ẹsin Fáráò, kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́sin rẹ̀ wọ inú òkun, Olúwa mú kí omi òkun padà bò wọ́n mọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rìn lórí ìyàngbẹ ilẹ̀ la òkun kọjá.
20 Míríámù wòlíì obìnrin, arábìnrin Árónì, mú ohun èlò orin ni ọwọ́ rẹ̀, àwọn obìnrin ti ó tẹ̀lé pẹ̀lú mú ohun èlò orin wọ́n sì ń jó.
21 Míríámà kọrin sí wọn báyìí pé:“Ẹ kọrin sí OlúwaNítorí òun ni ológo jùlọẸṣin àti ẹni tí ó gùn únNi òun bi subú sínú òkun.”