24 Àwọn ènìyàn ń kùn sí Mósè wí pé, “Kí ni àwa yóò mu?”
25 Mósè sì ké pe Olúwa, Olúwa sì fi igi kan hàn án, ó sì sọ igi náà sínú omi, omi náà sì dùn.Níbẹ̀ ni Olúwa ti gbé ìlànà àti òfin kalẹ̀ fún wọn, níbẹ̀ ni ó sì ti dán wọn wò.
26 Ó wí pé, “Bí ìwọ bá fetísílẹ̀ dáradára sí òfin Olúwa Ọlọ́run, ti ìwọ si ṣe ohun tí ó tọ́ ni ojú rẹ̀, ti ìwọ sì tẹ̀lé ohun tí ó pàṣẹ, ti ìwọ si pa ìlànà rẹ̀ mọ́. Èmi kì yóò jẹ́ kí èyíkéyìí nínú àwọn àrùn wọ̀n-ọn-nì ti mo mú wá sórí àwọn ará Éjíbítì wá sí ara rẹ, nítorí èmi ni Olúwa ti ó mú ọ lára da.”
27 Nígbà ti wọ́n dé Élímù, nibi ti kànga omi méjìlá (12) àti àádọ́rin (70) ọ̀pẹ gbé wà, wọ́n pàgọ́ ṣíbẹ̀ ni etí omi.