15 Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí i, wọ́n bi ara wọn léèrè pé, “Kí ni èyí?” Nítorí pé wọn kò mọ ohun tí i se.Mósè sì wí fún wọn pé, “Èyí ni oúnjẹ tí Olúwa fi fún un yín láti jẹ.
16 Èyí ni ohun tí Olúwa ti pàṣẹ: ‘Kí olúklùkù máa kó èyí ti ó tó fún un láti jẹ. Ẹ mú òṣùnwọ̀n ómérì kan (bí i líta méjì) fún ẹnikọ̀ọ̀kan ti ó wà nínú àgọ́ yín.’ ”
17 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe bí a ti sọ fún wọn; àwọn kan kó púpọ̀, àwọn kan kó kékeré.
18 Nígbà ti wọn fi òṣùwọ̀n ómérì wọ̀n-ọ́n-nì, ẹni ti ó kó púpọ̀ kò ní púpọ̀ jù, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó kó ìwọ̀nba kò ní kéré jù. Ẹnìkọ̀ọ̀kan kó ìwọ̀nba ti ó tó fún un.
19 Mósè sì wí fún wọ́n pé, “Kí ẹnikẹ́ni ó má ṣe kó pamọ́ lára rẹ̀ di òwurọ̀ ọjọ́ kejì.”
20 Ṣùgbọ́n, àwọn kan nínú wọn kò fetí sí Mósè; Wọ́n kó lára rẹ̀ pamọ́ di òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ohun ti wọ́n kó pamọ́ kún fún ìdin, ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ní rùn. Nítorí náà Mósè bínú sí wọn.
21 Ní òwúrọ̀, ni ojoojúmọ́ ni ẹnìkọ̀ọ̀kan ń lọ kó ìwọ̀nba ti ó tó fún un láti jẹ, bí òòrùn bá sì mú, a sì yọ́.