30 Nítorí náà, àwọn ènìyàn sinmi ní ọjọ́ keje.
31 Àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì sì pe oúnjẹ náà ní Mánà. Ó funfun bí irúgbìn kóríáńdà, ó sì dùn bí burẹ́dì fẹlẹfẹlẹ ti a fi oyin ṣe.
32 Mósè wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa pàṣẹ: ‘Ẹ mú òṣùnwọ̀n ómérì mánà kí ẹ sì pa á mọ́ de àwọn ìran ti ń bọ̀, kí wọn kí ó lè rí oúnjẹ ti èmi fi fún un yín jẹ ní ijù, nígbà tí mo mú un yín jáde ni ilẹ̀ Éjíbítì.’ ”
33 Nígbà náà ni Mósè sọ fún Árónì pe, “Mú ìkòkò kan, kí o sì kó mánà tí ó kún òṣùnwọ̀n ómérì kan sí inú rẹ̀, kí o sì gbé e kalẹ̀ ni iwájú Olúwa láti tọ́jú rẹ̀ pamọ́ de àwọn ìran ti ń bọ̀.”
34 Bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè, Árónì gbé mánà sí iwájú ẹ̀rí láti pa á mọ́.
35 Àwọn ará Ísírẹ́lì jẹ mánà fún ogójì ọdún títí wọ́n fi dé ilẹ̀ Kénánì ni ibi ti èso ti wà fún wọn láti jẹ; Wọ́n jẹ mánà títí tí wọ́n fi dé ilẹ̀ agbégbé Kénánì.
36 (Ọ̀sùnwọn ómérì kan sì jẹ́ ìdákan nínú ìdá-mẹ́wàá éfà.)