5 Ní ọjọ́ kẹfà, ki wọn kó ìlọ́po méjì èyí ti wọn ń ko ni ojoojúmọ́ tẹ́lẹ̀.”
6 Mósè àti Árónì sọ fún gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, “Ní ìrọ̀lẹ́, ẹ̀yin yóò mọ̀ pé Olúwa ni ó mú un yín jáde láti Éjíbítì wá.
7 Ní òwúrọ̀, ẹ̀yin yóò ri ògo Olúwa, nítorí òun ti gbọ́ kíkùn tí ẹ kùn sí i. Ta ni àwa ti ẹ̀yin yóò máa kùn sí wa?”
8 Mósè tún wí pé, “Ẹ̀yin yóò mọ pé Olúwa ni, nígbà ti ó bá fún un yín ni ẹran ni ìrọ̀lẹ̀ àti gbogbo oúnjẹ ti ẹ̀yin ń fẹ́ ni òwúrọ̀, nítorí kíkún ti ẹ̀yin ń kùn sí i. Ta ni àwa? Ẹ̀yin kò kùn sí àwa, Olúwa ni ẹ̀yin kùn sí i.”
9 Nígbà náà ni Mósè sọ fún Árónì pe, “Sọ fún gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pe, ‘Ẹ wá sí iwájú Olúwa, nítorí òun ti gbọ́ kíkùn yín.’ ”
10 Ó sì ṣe bí Árónì ti ń bá gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, wọn si bojúwo ìhà ijù, sì kíyèsi ògo Olúwa si farahàn ni àwọ̀-sánmọ̀.
11 Olúwa sọ fún Mósè pé,