1 Ní oṣù kẹ́ta tí àwọn Ísírẹ́lì jáde kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítì, ni ọjọ́ náà gan an ni wọ́n dé ihà Ṣínáì.
2 Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n gbéra kúrò ní Réfídímù, wọ́n wọ ijù Ṣínáì, wọ́n sì tẹ̀dó ṣíbẹ̀ ní iwájú òkè Ṣínáì.
3 Mósè sì gòkè tọ Ọlọ́run lọ. Olúwa sì ké pè é láti orí òkè náà wá pé, “Èyí ni ìwọ yóò sọ fún ilé Jákọ́bù àti ohun tí ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì:
4 ‘Ẹ̀yin ti rí ohun tí mo ti ṣe sí àwọn ará Éjíbítì, àti bí mo ti gbé e yín ní apá ìyẹ́ idì.
5 Nísinsìn yìí, bí ẹ̀yin bá ṣe ìgbọ́rán sí mi dé ojú àmì, tí ẹ sì pa májẹ̀mu mi mọ́, nígbà náà ni ẹ̀yin ó jẹ́ ìṣúra fún mi ju gbogbo orílẹ̀ èdè yóòkù lọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ayé ni tèmi.
6 Ẹ̀yin yóò sì máa jẹ́ ilẹ ọba àwọn àlùfáà fún mi, orílẹ̀ èdè mímọ́.’ Ìwọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ ti ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.”