1 Ó sì ṣe, ọkùnrin ará ilé Léfì kan fẹ́ ọmọbìnrin ará Léfì kan ni ìyàwó.
2 Obìnrin náà sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan. Nígbà tí ó rí í pé ọmọ náà rẹwà, ó gbé ọmọ náà pamọ́ fún oṣù mẹ́ta.
3 Ṣùgbọ́n nígbà tí kò le è gbé e pamọ́ mọ́, ó fi ewé pápírúsì hun apẹ̀rẹ̀, ó sì fi ọ̀dà ati òjé igi sán apẹ̀rẹ̀ náà. Ó sì tẹ́ ọmọ náà sínú rẹ̀, ó sì gbe é sí inú esùnsún ni etí odò Náílì.
4 Arábìnrin rẹ̀ dúró ni òkèèrè láti wo ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ọmọ náà.
5 Nígbà náà ni ọmọbìnrin Fáráò sọ̀kalẹ̀ wá sí etí odò Náílì láti wẹ̀, àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ sì ń rìn ni etí bèbè odò. Ó sì ri apẹ̀rẹ̀ náà ni àárin esùnsún, ó sì rán ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin kan láti lọ gbé e wá,
6 ó sí i, ó sì rí ọmọ náà. Ọmọ náà ń sunkún, àánú ọmọ náà sì ṣe é. Ó wí pé “Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Hébérù ni èyí.”