10 Ṣùgbọ́n ọjọ́ keje ni ọjọ́ ìsinmi Olúwa Ọlọ́run rẹ. Nínú rẹ̀ ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́kiṣẹ́ kan: ìwọ, àti ọmọ rẹ ọkunrìn àti ọmọ rẹ obìnrin, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ ọkùnrin tàbí ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ obìnrin, tàbí ẹran ọ̀sìn rẹ, àti àlejò rẹ tó wà ní nínú ibodè rẹ.
11 Nítorí ní ọjọ́ mẹ́fà ni Ọlọ́run dá ọ̀run àti ayé, òkun àti gbogbo nǹkan tí ó wà nínú rẹ̀, ṣùgbọ́n ó sinmi ní ọjọ́ keje. Nítorí náà ni Olúwa ṣe bùkún ọjọ́ ìsinmi tí ó sì yà á sí mímọ́.
12 “Bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ, kí ọjọ́ rẹ bá a le pẹ́ ní orí ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ.
13 “Ìwọ kò gbọdọ̀ pa ènìyàn.
14 “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà.
15 “Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè.
16 “Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké sí ẹnìkejì rẹ.