12 “Bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ, kí ọjọ́ rẹ bá a le pẹ́ ní orí ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ.
13 “Ìwọ kò gbọdọ̀ pa ènìyàn.
14 “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà.
15 “Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè.
16 “Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké sí ẹnìkejì rẹ.
17 “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojú kòkòrò sí ilé aládùúgbò rẹ. Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojú kòkòrò sí aya aládùúgbò rẹ̀, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ọkùnrin tàbí sí ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin, akọ màlúù rẹ̀ tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ tàbí ohunkóhun tí ó jẹ́ ti aládùúgbò rẹ.”
18 Nígbà tí àwọn ènìyàn náà rí mọ̀nàmọ́ná tí wọ́n sí gbọ́ ohùn ìpè àti èéfín tí ń rú láti orí òkè, tí wọ́n sì gbọ́ sísán àrá, dídún ìpè kíkankíkan; wọ́n dúró ní òkèrè wọ́n sì ń gbọ̀n sìgàsìgà fún ìbẹ̀rù.