13 Ṣùgbọ́n bí kò bá mọ̀ ọ́n mọ̀ pa á, tí ó bá jẹ́ (àmúwá) ìfẹ́ Ọlọ́run ni, òun yóò lọ sí ibi tí èmi yóò yàn fún un.
14 Ṣùgbọ́n tí ó bá arákùnrin rẹ̀, tí ó sì fi ẹ̀tàn pa á. Ẹ mú un kúrò ní iwájú pẹpẹ mi kí ẹ sì pa á.
15 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa baba tàbí ìyá rẹ̀, pípa ni a ó pa á.
16 “Ẹnikẹ́ni ti ó bá ji ènìyàn gbé, tí ó sì tà á tàbí tí ó fi ì pamọ́, pípa ni a ó pa á.
17 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣépè fún baba tàbí ìyá rẹ̀, pípa ni a ó pa á.
18 “Bí àwọn ọkùnrin méjì bá ń jà, ti ọ̀kan sọ òkúta tàbí fi ẹ̀ṣẹ́ lu ẹnìkejì rẹ̀, tí ó sì pa á lára, ti irú ìpalára bẹ́ẹ̀ mu kí ó wà lórí ìdùbúlẹ̀ àìsàn,
19 Ẹni tó lu ẹnìkejì rẹ̀ kò ní ní ẹ̀bi, níwọ̀n ìgbà ti ẹni tí a lù bá ti lè dìde, tí ó sì lé è fi ọ̀pá ìtilẹ̀ ní ọwọ rẹ̀ rìn káàkiri. Ẹni náà ni láti san owo ti ó fi tọ́jú ara rẹ̀ padà fún un, lẹ́yìn ìgbà tí ara rẹ̀ bá ti yá tan pátápátá.