16 “Ṣe àjọ̀dún ìkórè pẹ̀lú èso àkọ́so ọ̀gbìn oko rẹ.“Ṣe àjọ̀dún àkójọ oko rẹ ní òpin ọdún, nígbà tí ìwọ bá kó irè oko rẹ jọ tan.
17 “Ní ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni àwọn ọkùnrin yín yóò máa wá fi ara hàn ní iwájú Olúwa Ọlọ́run.
18 “Ìwọ kò gbọdọ̀ rú ẹbọ ẹ̀jẹ̀ sí mi ti òun ti búrẹ́di tó ní ìwúkàrà.“Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rá ẹbọ àjọ mi ni kò gbọdọ̀ kù títí di òwúrọ̀.
19 “Mú èso àkọ́so ilẹ̀ rẹ tí ó dára jùlọ wá sí ilé Olúwa Ọlọ́run rẹ.“Ìwọ kò gbọdọ̀ fi omi ọmú ìyá ewúrẹ́ bọ ọmọ ewúrẹ́.
20 “Kíyèsí èmi rán ańgẹ́lì kan lọ ní iwájú rẹ, láti ṣọ́ ọ ni ọ̀nà àti láti mú ọ dé ibi ti mo ti pèsè sílẹ̀ fún.
21 Fi ara bálẹ̀, kí o sì fetísílẹ̀ sí i, kí o sì gba ohùn rẹ̀ gbọ́; má ṣe sọ̀tẹ̀ sí i, nítorí kò ní fi àìsedédé yín jin yín, orúkọ mi wà lára rẹ̀.
22 Bí ìwọ bá fetísílẹ̀ dáradára sí ohùn rẹ̀ tí ẹ sì se ohun gbogbo ti mo ní kí ẹ ṣe, èmi yóò jẹ́ ọ̀tá àwọn ọ̀tá yín. Èmi yóò sì fóòrò àwọn tí ń fóòrò yín.