1 Ní ìgbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé, “Gòkè tọ Olúwa wá, ìwọ àti Árónì, Nádábú àti Ábíhù àti àádọ́rin (70) àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì. Ẹ̀yin kì ó sìn ni òkèèrè réré.
2 Ṣùgbọ́n Mósè nìkan ṣoṣo ni yóò súnmọ́ Olúwa; àwọn tókù kò gbọdọ̀ súnmọ́ tòsí ibẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn kò gbọdọ̀ gòkè wá pẹ̀lú rẹ̀.”
3 Nígbà ti Mósè lọ láti sọ fún àwọn ènìyàn, gbogbo ọ̀rọ̀ àti òfin Olúwa, wọ́n wí ní ohùn kan pé, “Gbogbo ohun ti Olúwa wí ni àwa yóò ṣe.”
4 Nígbà náà ni Mósè kọ gbogbo ohun tí Olúwa sọ sílẹ̀.Ó dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó sì mọ pẹpẹ ni ẹsẹ̀ òkè náà. Ó se ọ̀wọ́n òkúta méjìlá. Èyí ti ó dúró fún àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá.
5 Nígbà náà ni ó rán àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Ísírẹ́lì, wọ́n sì rúbọ sísun, wọ́n fi ọ̀dọ́ màlúù rú ẹbọ àlàáfíà si Olúwa.
6 Mósè bu ìlàjì ẹ̀jẹ̀ ẹran sínú abọ́, ó sì fi ìlàjì tókù wọn ara pẹpẹ.