4 Wọ̀nyí ni àwọn aṣọ tí wọn yóò dá: ìgbàyà kan, ẹ̀wù èfòdì, ọ̀já àmùrè kan, ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ ọlọ́nà, fìlà àti aṣọ ìgúnwà. Kí wọn kí ó dá àwọn aṣọ mímọ́ yìí fún Árónì arákùnrin rẹ àti àwọn ọmọ rẹ̀, kí wọn kí ó lè sìn mí gẹ́gẹ́ bí àlùfáà.
5 Wọn yóò sì lo wúrà, aṣọ aláró, elésèé àlùkò àti ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ dáradára.
6 “Wọn yóò sì dá ẹ̀wù èfòdì ti wúrà, tí aṣọ aláró, elésèé àlùkò àti ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókún wíwẹ́ iṣẹ́ ọlọ́nà.
7 Kí ó ni aṣọ èjìká méjì tí a so mọ́ igun rẹ̀ méjèèjì, kí a lè so ó pọ̀.
8 Àti onírúurú ọnà ọ̀já rẹ̀, tí ó wà ni orí rẹ̀, yóò rí bákan náà, gẹ́gẹ́ bi iṣẹ́ rẹ̀, tí wúrà, ti aṣọ aláró, òdòdó àti ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́.
9 “Ìwọ yóò sì mú òkúta óníkísì méjì, ìwọ yóò sì fún orúkọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sára wọn.
10 Ní ti ìbí wọn, orúkọ àwọn mẹ́fà sára òkúta kan àti orúkọ àwọn mẹ́fà tókù sára òkúta kejì.