1 “Èyí ni ohun tí ìwọ yóò ṣe láti yà wọ́n sí mímọ́, nítorí kí wọn lè máa àti láti máa sìn se àlùfáà fún mi: Mú ọ̀dọ́ akọ màlúù kan àti àgbò méjì tí kò ní àbùkù.
2 Láti ara ìyẹ̀fun aláìwú dídùn, ṣe àkàrà àti àkàrà tí a pò pẹ̀lú òróró, àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ aláìwú tí a da òróró sí.
3 Ìwọ yóò sì kó wọn sínú àpẹ̀rẹ̀ kan, ìwọ yóò sì mú wọn wà nínú apẹ̀rẹ̀ náà—papọ̀ pẹ̀lú akọ màlúù àti àgbò méjì náà.
4 Nígbà náà ni ìwò yóò mú Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ, ìwọ yóò sì fi omi wẹ̀ wọ́n.
5 Ìwọ yóò sì fi ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ Árónì, àti aṣọ ìgúnwà éfódì, àti éfódì, àti ìgbàyà, kí ó sì fi onírúurú-ọnà ọ̀já ẹ̀wù èfòdì dìí.