10 “Ìwọ yóò sì mú akọ màlúù wá ṣíwájú àgọ́ àjọ, Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò sì fi ọwọ́ lé wọn ní orí.
11 Ìwọ yóò sì pa àwọn akọ màlúù náà níwájú Olúwa ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ.
12 Ìwọ yóò sì mú nínú ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù náà, ìwọ yóò sì fi ìka rẹ tọ́ ọ sára ìwo pẹpẹ náà, kí o sì da gbogbo ẹ̀jẹ̀ tó kù sí ìṣàlẹ̀ pẹpẹ náà.
13 Kí o mú gbogbo ọ̀rá tí ó yí inú ká, èyí tí ó bo ẹ̀dọ̀ àti ìwé méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá tí ó wà lára wọn, ìwọ yóò sì sun wọ́n lórí pẹpẹ.
14 Ṣùgbọ́n fi iná sun ẹran akọ màlúù, awọ rẹ̀ àti ìgbẹ́ rẹ̀ lẹ́yìn òde. Ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni.
15 “Ìwọ yóò sì mú àgbò kan, Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò sì fi ọwọ́ wọn lé àgbò náà lórí.
16 Ìwọ yóò sì pa àgbò náà, ìwọ yóò sì mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ìwọ yóò wọ́n-ọn sí pẹpẹ ni gbogbo ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.