Ékísódù 29:16-22 BMY

16 Ìwọ yóò sì pa àgbò náà, ìwọ yóò sì mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ìwọ yóò wọ́n-ọn sí pẹpẹ ni gbogbo ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.

17 Ìwọ yóò sì gé àgbò náà sí wẹ́wẹ́, ìwọ yóò sì fọ inú àti àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀, ìwọ yóò sì tò wọ́n pẹ̀lú orí rẹ̀ lé ara wọn.

18 Nígbà náà ni ìwọ yóò sun àgbò náà lórí pẹpẹ. Ẹbọ sísun ni sí Olúwa, olóòórùn dídùn ni, ẹbọ ti a fi iná se sí Olúwa ni.

19 “Ìwọ yóò mú àgbò kejì, Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò fi ọwọ́ wọn lé àgbò náà lórí.

20 Ìwọ yóò sì pa àgbò náà, ìwọ yóò mú nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ìwọ yóò sì tọ́ ọ sí etí ọ̀tún Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀, sí àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún wọn, àti sí àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún wọn. Ìwọ yóò sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà sí pẹpẹ lórí àti ní gbogbo ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.

21 Ìwọ yóò mú nínú ẹ̀jẹ̀ tí ó wà lórí pẹpẹ àti nínú òróró ìtasórí, ìwọ yóò sì wọ́n-ọn sára Árónì àti sára aṣọ rẹ̀, sára àwọn ọmọ rẹ àti sára aṣọ wọn. Nígbà náà ni òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ àti aṣọ wọn yóò di mímọ́.

22 “Ìwọ yóò mú lára ọ̀rá àgbò náà, ìrù tí ó lọ́ràá, ọ̀rá tí ó yí inú ká, èyí ti ó bo ẹ̀dọ̀, iwe méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá tí ó wà lára wọn àti itan ọ̀tún. (Èyí ni àgbò fún ìyàsímímọ́).