43 níbẹ̀ sì tún ni èmi yóò pàdé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, a ó sì fi ògo mi ya àgọ́ náà sí mímọ́.
44 “Bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ya àgọ́ àjọ náà sí mímọ́ àti pẹpẹ náà, èmi yóò sì ya Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ sí mímọ́ láti máa ṣe iṣẹ́ bí àlùfáà fún mi.
45 Nígbà náà ni èmi yóò máa gbé láàrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, èmi yóò sì máa ṣe Ọlọ́run wọn.
46 Wọn yóò sì mọ̀ pé èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn, ẹni tí ó mú wọn jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì wá, nítorí kí èmi lè máa gbé àárin wọn. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn.