3 Nígbà náà ni Mósè sọ pé, “Èmi yóò lọ wo ohun ìyanu yìí, ìdí tí iná kò fi jó igbó run.”
4 Nígbà tí Olúwa rí i pe Mósè ti lọ láti lọ wò ó, Ọlọ́run ké pè é láti àárin igbó náà, “Mósè! Mósè!!”Mósè sì dáhùn ó wí pé, “Èmi nì yìí.”
5 Ọlọ́run sì wí fún Mósè pé, “Má ṣe súnmọ́ ìhín yìí, bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀, nítorí ibi tí ìwọ dúró sí i nì ilẹ̀ mímọ́ ni.”
6 Nígbà náà ní ó wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run baba yín, Ọlọ́run Ábúráhámù, Ọlọ́run Ísáákì àti Ọlọ́run Jákọ́bù.” Nítorí ìdí èyí, Mósè fi ojú rẹ̀ pamọ́, nítorí ó bẹ̀rù láti wo ojú Ọlọ́run.
7 Ọlọ́run si wí pé, “Èmí ti rí ìpọ́njú àwọn ènìyàn mi ní ilẹ̀ Éjíbítì, mo sì ti gbọ́ ohùn igbe wọn nítorí àwọn akóniṣiṣẹ́ wọn. Ìyà tí ń jẹ wọ́n sì kan mi lára.
8 Èmi sì ti sọ̀kalẹ̀ wá láti gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ará Éjíbítì, àti láti mú wọn gòkè kúrò ní ilẹ̀ náà lọ sí ilẹ̀ tí ó dára tí ó sì ní ààyè, àní ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin; ibùgbé àwọn ará Kénánì, Hétì, Ámórì, Pérésì, Hífì àti Jébúsì.
9 Ǹjẹ́ nísinsìnyìí, wò ó, igbe àwọn ará Ísírẹ́lì ti dé ọ̀dọ̀ mi, Èmi sì ti rí bí àwọn ará Éjíbítì ti se ń gbà ń jẹ wọ́n ní ìyà.