6 Nígbà náà ní ó wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run baba yín, Ọlọ́run Ábúráhámù, Ọlọ́run Ísáákì àti Ọlọ́run Jákọ́bù.” Nítorí ìdí èyí, Mósè fi ojú rẹ̀ pamọ́, nítorí ó bẹ̀rù láti wo ojú Ọlọ́run.
7 Ọlọ́run si wí pé, “Èmí ti rí ìpọ́njú àwọn ènìyàn mi ní ilẹ̀ Éjíbítì, mo sì ti gbọ́ ohùn igbe wọn nítorí àwọn akóniṣiṣẹ́ wọn. Ìyà tí ń jẹ wọ́n sì kan mi lára.
8 Èmi sì ti sọ̀kalẹ̀ wá láti gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ará Éjíbítì, àti láti mú wọn gòkè kúrò ní ilẹ̀ náà lọ sí ilẹ̀ tí ó dára tí ó sì ní ààyè, àní ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin; ibùgbé àwọn ará Kénánì, Hétì, Ámórì, Pérésì, Hífì àti Jébúsì.
9 Ǹjẹ́ nísinsìnyìí, wò ó, igbe àwọn ará Ísírẹ́lì ti dé ọ̀dọ̀ mi, Èmi sì ti rí bí àwọn ará Éjíbítì ti se ń gbà ń jẹ wọ́n ní ìyà.
10 Ǹjẹ́ nísinsínyìí, lọ, Èmi yóò rán ọ sí Fáráò láti kó àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì.”
11 Ṣùgbọ́n Mósè wí fún Ọlọ́run pé, “Ta ni èmi, tí èmi yóò tọ Fáráò lọ, ti èmi yóò sì kó àwọn ará Ísírẹ́lì jáde kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítì?”
12 Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Mósè pé, “Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ̀. Èyí ni yóò jẹ́ àmì fún ọ, tí yóò fihàn pé Èmi ni ó rán ọ lọ; Nígbà tí ìwọ bá kó àwọn ènìyàn náà jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì, ẹ̀yin yóò sin Ọlọ́run ni orí òkè yìí.”