8 tábìlì àti ohun èlò rẹ̀, ọ̀pá fìtílà tí ó jẹ́ kìkì wúrà àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, pẹpẹ tùràrí,
9 pẹpẹ ẹbọ sísun àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, agbada pẹ̀lú ẹṣẹ̀ rẹ̀
10 àti aṣọ híhun pẹ̀lú, papọ̀ pẹ̀lú aṣọ mímọ́ fún Árónì àlùfáà àti aṣọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ bí àlùfáà,
11 òróró ìtasórí àti tùràrí olóòórùn dídùn fún ibi mímọ́. Kí wọ́n se wọ́n gẹ́gẹ́ bí mo ṣe paṣẹ fún ọ.”
12 Olúwa wí fún Mósè pé,
13 “Kí ìwọ kí ó sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Ẹ̀yín gbọdọ̀ máa pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́. Èyí ni yóò jẹ́ àmì láàrin èmi àti ẹ̀yin fún ìrandíran tó ń bọ̀, nítorí kí ẹ̀yin lè mọ̀ pé èmi ni Olúwa, ẹni tí ó yà yín sí mímọ́.
14 “ ‘Nítorí náà, kí ẹ̀yin kí ó máa pa ọjọ́ ìsinmi mọ́, nítorí mímọ́ ni fún un yín. Ẹnikẹ́ni tí ó bá bà á jẹ́, ni a óò pa; ẹnikẹ́ni tí ó bá se iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà ni a óò gé kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ.