13 Rántí àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ Ábúráhámù, Ísáákì àti Ísírẹ́lì, ẹni tí ìwọ búra fún fúnraàrẹ: ‘tí o wí fún wọn pé, èmi yóò mú irú ọmọ rẹ pọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, èmi yóò sì fún irú ọmọ rẹ ní gbogbo ilẹ̀ tí mo ti pinnu fún wọn, yóò sì jẹ́ ogún ìní wọn láéláé.’ ”
14 Nígbà náà ni Olúwa yí ọkàn padà, kò sì mú ìparun náà tí ó sọ wá sórí àwọn ènìyàn rẹ̀ mọ́.
15 Mósè sì yípadà, ó sì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà pẹ̀lú okuta wàláà ẹ̀rí méjì ní ọwọ́ rẹ̀. Wọ́n kọ ìwé síhà méjèèjì, iwájú àti ẹ̀yin.
16 Iṣẹ́ Ọlọ́run sì ni wàláà náà; ìkọ̀wé náà jẹ́ ìkọ̀wé Ọlọ́run, a fín-in sára àwọn òkúta wàláà náà.
17 Nígbà tí Jóṣúà gbọ́ ariwo àwọn ènìyàn tí wọ́n ń kígbe, ó sọ fún Mósè pé, “Ariwo ogun wà nínú àgọ́.”
18 Mósè dáhùn pé:“Kì í ṣe ariwo fún ìṣẹ́gun,kì í ṣe ariwo fún aṣẹ́gun;ohùn àwọn tí ń kọrin ni mo gbọ́.”
19 Nígbà tí Mósè dé àgọ́, ó sì rí ẹgbọrọ màlúù náà àti ijó, ìbínú rẹ gbóná, ó sì ju pálí ọwọ́ rẹ̀ sílẹ̀, ó sì fọ́ wọn sí wẹ́ẹ́wẹ́ ní ìṣàlẹ̀ òkè náà.