29 Nígbà tí Mósè sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè Ṣínáì pẹ̀lú wàláà ẹ̀rí méjì ní ọwọ́ rẹ̀, òun kò mọ̀ pé ojú òun ń dán nítorí ó bá Olúwa sọ̀rọ̀.
30 Nígbà tí Árónì àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí Mósè, ojú rẹ̀ ń dán, ẹ̀rù sì ń bà wọ́n láti sún mọ́ ọn.
31 Ṣùgbọ́n Mósè pè wọn; Árónì àti gbogbo àwọn olórí àjọ padà wá bá a, ó sì bá wọn sọ̀rọ̀.
32 Lẹ́yìn èyí gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sún mọ́ ọn, ó sì fún wọn ní gbogbo àṣẹ tí Olúwa fún-un lórí òkè Ṣínáì.
33 Nígbà Mósè parí ọ̀rọ̀ sísọ fún wọn. Ó fi ìbòjú bo ojú rẹ̀.
34 Ṣùgbọ́n nígbàkígbà tí ó bá wà níwájú Olúwa láti bá a sọ̀rọ̀, á sí ìbòjú náà títí yóò fi jáde. Nígbà tí ó bá sì jáde, á sì sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ohun tí a ti pa láṣẹ fún-un,
35 wọ́n sì rí i pé ojú rẹ̀ ń dán. Mósè á sì tún fi ìbòjú bo ojú rẹ̀ títí á fi lọ bá Olúwa sọ̀rọ̀.