12 Àpótí náà pẹ̀lú ọ̀pá rẹ̀, ibò àánú àti aṣọ títa náà tí ó síji bòó;
13 Tábìlì náà pẹ̀lú òpó rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀ àti àkàrà ìfihàn náà;
14 Ọ̀pá fìtílà tí ó wà fún títanná pẹ̀lú ohun èlò rẹ̀, fìtílà àti òróró fún títanná;
15 Pẹpẹ tùràrí náà pẹ̀lú ẹsẹ̀ rẹ̀, òróró ìtasórí àti tùràrí dídùn; aṣọ títa fún ọ̀nà ìlẹ̀kùn ní ẹnu ọ̀nà sí Àgọ́ náà;
16 Pẹpẹ ẹbọ sísun pẹ̀lú ojú àrò idẹ rẹ̀, òpó rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀; agbada idẹ pẹ̀lú ẹsẹ̀ rẹ̀;
17 aṣọ títa ti àgbàlá pẹ̀lú, ọ̀wọ́n àti ihò ìtẹ̀bọ̀ rẹ̀ àti aṣọ títa fún ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà;
18 Èèkàn àgọ́ náà fún Àgọ́ náà àti fún àgbàlá àti okùn wọn;