2 Fún ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ọjọ́ keje yóò jẹ́ ọjọ́ mímọ́ fún yín, ọjọ́ ìsinmi ni sí Olúwa. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ kankan ni ọjọ́ náà ní a ó pa.
3 Ẹ má se dáná kankan ní ibùgbé yín ní ọjọ́ ìsinmi.”
4 Mósè sọ fún gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa pa láṣẹ:
5 Láti inú ohun tí ẹ ni ni kí ẹ ti mú ọrẹ fún Olúwa. Ẹnikẹ́ni tí ọ́ bá fẹ́ ni kí ó mú ọrẹ fún Olúwa ní ti wúrà, fàdákà àti idẹ;
6 aṣọ aláró, elésèé àlùkò, òdòdó àti ọ̀gbọ̀ dáradára; àti irun ewúrẹ́;
7 awọ àgbò tí a kùn ní pupa àti awọ màlúù; odò igi kaṣíá;
8 òróró ólífì fún títan iná; olóòórùn fún òróró ìtasórí, àti fún tùràrí dídùn;