20 Gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì kúrò níwájú Mósè,
21 Olúkúlùkù ẹni tí ó fẹ́ àti ẹni tí ọkàn rẹ̀ gbé sókè wá, wọ́n sì mú ọrẹ fún Olúwa, fún isẹ́ Àgọ́ àjọ, fún gbogbo ìsìn rẹ̀ àti fún asọ mímọ́ náà.
22 Gbogbo àwọn tí ó fẹ́, ọkùnrin àti obìnrin, wọ́n wá wọ́n sì mú onírúurú ìlẹ̀kẹ wúrà: òrùka etí, òrùka àti ọ̀sọ́. Gbogbo wọn mú wúrà gẹ́gẹ́ bí ọrẹ wá fún Olúwa.
23 Olúkúlùkù ẹni tí ó ni aṣọ aláró elésèé àlùkò, òdòdó àti ọ̀gbọ̀ dáradára, tàbí irun ewúrẹ́, awọ àgbò tí a rì ní pupa tàbí awọ màlúù odò, kí ó mú wọn wá.
24 Àwọn tí ó mú ọrẹ fàdákà tàbí idẹ wá, mú ọrẹ wá fún Olúwa, àti olúkúlùkù ẹni tí ó ní igi kasíà fún ipa kankan nínú iṣẹ mú un wá.
25 Gbogbo àwọn obìnrin tí ó ní ọgbọ́n ríran owú pẹ̀lú ọwọ́ rẹ̀, kí ó mú èyí ti ó ti ran wá ti aláró, ti elésèé àlùkò, ti òdòdó tàbí ti ọ̀gbọ̀ dáradára.
26 Gbogbo àwọn obìnrin tí ó fẹ́, tí ó sì ní ọgbọ́n ń ran òwú irun ewúrẹ́