26 Gbogbo àwọn obìnrin tí ó fẹ́, tí ó sì ní ọgbọ́n ń ran òwú irun ewúrẹ́
27 Àwọn olórí mú òkúta óníkísì wá láti tò ó lórí ẹ̀wù éfódì àti igbáàyà.
28 Wọ́n sì tún mú olóòrùn àti òróró ólífì wá fún títanná àti fún òróró ìtasórí àti fún tùràrí dídùn.
29 Gbogbo àwọn ènìyàn Isirẹli ọkùnrin àti obìnrin ẹni tí ó fẹ́ mú ọrẹ àtinúwá fún Olúwa fún gbogbo iṣẹ́ tí Olúwa ti pa láṣẹ fún wọn láti se nípaṣẹ̀ Mósè.
30 Nígbà náà ni Mósè wí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, “Wò ó, Olúwa ti yan Bésálélì ọmọ Úrì, ọmọ Húrì, ti ẹ̀yà Júdà,
31 Ó sì ti fi ẹ̀mí Ọlọ́run kún-un, pẹ̀lú ọgbọ́n, agbára, ìmọ̀ àti gbogbo onírúurú isẹ́ ọnà
32 Láti má a se aláràbarà iṣẹ́ ní ti wúrà, fàdákà àti idẹ,