9 Òkúta óníkìsì àti òkúta tí a tò sí ẹ̀wù èfòdì àti igbáàyà.
10 “Gbogbo ẹni tí ó ní ọgbọ́n láàrin yín, kí ó wa, kí ó sì wá se gbogbo ohun tí Olúwa ti pa láṣẹ:
11 Àgọ́ náà pẹ̀lú àgọ́ rẹ àti ìbòrí rẹ̀, kọ́kọ́rọ́ rẹ̀, pákó rẹ̀, ọ̀pá rẹ̀, ọ̀wọ́n rẹ̀ àti ihò ìtẹ̀bọ̀ rẹ̀;
12 Àpótí náà pẹ̀lú ọ̀pá rẹ̀, ibò àánú àti aṣọ títa náà tí ó síji bòó;
13 Tábìlì náà pẹ̀lú òpó rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀ àti àkàrà ìfihàn náà;
14 Ọ̀pá fìtílà tí ó wà fún títanná pẹ̀lú ohun èlò rẹ̀, fìtílà àti òróró fún títanná;
15 Pẹpẹ tùràrí náà pẹ̀lú ẹsẹ̀ rẹ̀, òróró ìtasórí àti tùràrí dídùn; aṣọ títa fún ọ̀nà ìlẹ̀kùn ní ẹnu ọ̀nà sí Àgọ́ náà;