17 Wọ́n sì pa àádọ́ta (50) ajábó sí ìsẹ́tí ìkángun aṣọ títa ní apá kan, wọ́n sì tún pa ajábó mìíràn sí ìsẹ́tí ìkángun aṣọ títa ní apá ibòmíràn.
18 Wọ́n ṣe àádọ́ta (50) ìkọ́ idẹ láti so Àgọ́ náà pọ̀ kí o lè jẹ́ ọ̀kan.
19 Wọ́n sì ṣe ìbòrí àwọ àgbò tí a rì ní pupa, àti ìbòrí màlúù odò lórí rẹ̀.
20 Wọ́n ṣe pákó igi kaṣíá tí ó dúró fún Àgọ́ náà.
21 Ọ̀kọ̀ọ̀kan pákó náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní gíga àti ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ní fífẹ̀,
22 pẹ̀lú ìtẹ̀bọ̀ méjì tí ó kọjú sí ara wọn. Wọ́n ṣe gbogbo pákó Àgọ́ náà bí èyí.
23 Wọn ṣe ogún pákó sí ìhà gúsù Àgọ́ náà.