3 Wọ́n gba gbogbo ọrẹ tí àwọn ọmọ Isirẹli ti mú wá lọ́wọ́ Mósè fún kíkọ́ ibi mímọ́ náà. Àwọn ènìyàn sì ń mú ọrẹ àtinúwá wá ní àràárọ̀.
4 Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n oníṣẹ́ ọnà tí wọn ń ṣe gbogbo iṣẹ́ ibi mímọ́ náà fi iṣẹ́ wọn sílẹ̀.
5 Mósè sì wí pé, “Àwọn ènìyàn mú púpọ̀ wá fún síṣe iṣẹ́ náà ju bi Olúwa ti pa á láṣẹ láti ṣe lọ.”
6 Mósè sì pàṣẹ, wọ́n sì rán iṣẹ́ yìí sí gbogbo ibùdó: “Kí ọkùnrin tàbí obìnrin má ṣe ṣe ohun kankan bí ọrẹ fún ibi mímọ́ náà mọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni a dá àwọn ènìyàn lẹ́kun láti mú un wá sí i,
7 nítorí ohun tí wọ́n ti ni ti ju ohun tí wọn fẹ́ fi ṣe gbogbo iṣẹ́ náà lọ.
8 Gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n ọkùnrin láàrin àwọn òṣìṣẹ́ ni wọ́n ṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú aṣọ títa mẹ́wàá ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára, tí aṣọ aláró, ti elésèé àlukò àti ti òdòdó, pẹ̀lú àwọn kérúbù ṣe iṣẹ́ sí wọn nípa ọgbọ́n iṣẹ́ ọnà.
9 Gbogbo aṣọ títa náà jẹ́ ìwọ̀n kan ìgbọ̀nwọ́ méjìdínlọ́gbọ̀n (28) ní gíga àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ní fífẹ̀.