7 nítorí ohun tí wọ́n ti ni ti ju ohun tí wọn fẹ́ fi ṣe gbogbo iṣẹ́ náà lọ.
8 Gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n ọkùnrin láàrin àwọn òṣìṣẹ́ ni wọ́n ṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú aṣọ títa mẹ́wàá ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára, tí aṣọ aláró, ti elésèé àlukò àti ti òdòdó, pẹ̀lú àwọn kérúbù ṣe iṣẹ́ sí wọn nípa ọgbọ́n iṣẹ́ ọnà.
9 Gbogbo aṣọ títa náà jẹ́ ìwọ̀n kan ìgbọ̀nwọ́ méjìdínlọ́gbọ̀n (28) ní gíga àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ní fífẹ̀.
10 Wọ́n sì pa aṣọ títa márùn-ún pọ̀ mọ̀ ara wọn, wọ́n sì tún ṣe bẹ́ẹ̀ sì márùn-ún tó kù.
11 Wọ́n sì pa ajábó aṣọ aláró ní etí aṣọ títa kan láti ìsẹ́tí rẹ̀ dé ibi òpin, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní o ṣe sí ìhà etí ikangun aṣọ títa kejì ní ibi òpin èkejì.
12 Àádọ́ta (50) ajábó ní ó pa lára aṣọ títa kan, àti àádọ́ta ajábó ni ó sì lò pa ní etí aṣọ títa tí ó wà ní ọ̀kánkán ara wọn.
13 Wọ́n sì ṣe àádọ́ta ìkọ́ wúrà, ó sì lò wọ́n láti fi kọ́ méjì aṣọ títa papọ̀ bẹ́ẹ̀ Àgọ́ náà sì di ọ̀kan.