10 Ó se tábìlì igi kaṣíá ìgbọ̀nwọ́ méjì ní gígùn, ìgbọ̀nwọ́ kan ní fífẹ̀, àti ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ní gíga.
11 Ó sì fi kìkì wúrà bòó, ó sì se ìgbátí yí i ká.
12 Ó sì tún ṣe etí ìbù ọwọ́ fífẹ̀ yìí ká, ó sì fi ìgbátí wúrà yí etí rẹ̀ ká.
13 Ó sì dá òrùka wúrà fún tábìlì náà, ó sì so wọ́n mọ́ igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, níbi tí ẹṣẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wà.
14 Àwọn òrùka náà wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ etí rẹ̀ láti gbá àwọn òpó náà mu láti máa fi gbé tábìlì náà.
15 Igi kaṣíá ni ó fi se òpó ti a fi ń gbé tábìlì náà, ó sì fi wúrà bò ó.
16 Ó sì ṣe àwọn ohun èlò tí ó wà lórí tábìlì náà ní kìkì wúrà, abọ́ rẹ̀, àwo rẹ, àwokòtò rẹ̀ àti ìgò rẹ̀ fún dída ọrẹ mímu jáde.