16 Ó sì ṣe àwọn ohun èlò tí ó wà lórí tábìlì náà ní kìkì wúrà, abọ́ rẹ̀, àwo rẹ, àwokòtò rẹ̀ àti ìgò rẹ̀ fún dída ọrẹ mímu jáde.
17 Ó sì se ọ̀pá fìtílà náà ní kìkì wúrà ó sì lù ú jáde, ọ̀pá rẹ̀, ìtànná ìfẹ́ rẹ̀, irudi rẹ àti ago rẹ̀, wọ́n jẹ́ òkan náà.
18 Ẹ̀ka mẹ́fà ní ó jáde láti ìhà ọ̀pá fìtílà náà mẹ́ta ní ìhà àkọ́kọ́ àti mẹ́ta ní ìhà èkejì.
19 Kọ́ọ̀bù mẹ́ta ni a se bí ìtànná alímóndì pẹ̀lú ìrùdí àti ìtànná wà ni ẹ̀ka kan, mẹ́ta sì tún wà ní ẹ̀ka mìíràn, bẹ́ẹ̀ ni ní ẹ̀ka mẹ́fẹ̀ẹ̀fà jáde lára ọ̀pá fìtílà.
20 Lára ọ̀pá fìtílà náà ni a se kọ́ọ̀bù mẹ́rin bí ìtànná alímóndì, ìrùdí rẹ̀ àti ìtànná rẹ̀:
21 Ìrùdí kan níṣàlẹ̀ ẹ̀ka méjì jáde lará ọ̀pá fìtílà náà, ìrùdí kejì níṣàlẹ̀ èkejì, àti ìrùdí kẹ́ta níṣàlẹ̀ ìrùdí ìkẹta-ẹ̀ka mẹ́fà lò wà lára gbogbo rẹ̀.
22 Ìrùdí náà àti ẹ̀ka wọn jẹ́ bákan náà, ó lù ú jáde ní kìkì wúrà.