2 Ó fi kìkì wúrà bò ó nínú àti lóde, ó sì fi wúrà gbà á léti yíká.
3 Ó sì dá òrùka wúrà mẹ́rin fún un, ó so wọ́n mọ́ ẹṣẹ̀ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, pẹ̀lú òrùka méjì ní ìhà kìn-ín-ní àti òrùka méjì ni ìhà kejì.
4 Ó sì tún ṣe òpó igi kaṣíà, ó sì bò wọ́n pẹ̀lú wúrà.
5 Ó sì kó àwọn òpó náà sínú òrùka ní ìhà àpótí náà láti máa fi gbé e.
6 Ó se ìbòrí àánú kìkì wúrà ìgbọ̀nwọ́ méjì àti ààbọ̀ gígùn rẹ̀ àti ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ni fífẹ̀ rẹ̀.
7 Ó sì se kérúbù méjì láti inú òlù wúrà ní òpin ìbòrí náà.
8 Ó se kérúbù kan ni òpin èkínní, ó sì tún ṣe kérúbù kejì sí èkejì; ní òpin méjèèjì ó ṣe ìtẹ́ àánú ìbòrí wọn.