4 Ó sì tún ṣe òpó igi kaṣíà, ó sì bò wọ́n pẹ̀lú wúrà.
5 Ó sì kó àwọn òpó náà sínú òrùka ní ìhà àpótí náà láti máa fi gbé e.
6 Ó se ìbòrí àánú kìkì wúrà ìgbọ̀nwọ́ méjì àti ààbọ̀ gígùn rẹ̀ àti ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ni fífẹ̀ rẹ̀.
7 Ó sì se kérúbù méjì láti inú òlù wúrà ní òpin ìbòrí náà.
8 Ó se kérúbù kan ni òpin èkínní, ó sì tún ṣe kérúbù kejì sí èkejì; ní òpin méjèèjì ó ṣe ìtẹ́ àánú ìbòrí wọn.
9 Àwọn kérúbù sì na ìyẹ́ apá wọn sókè sí i, ó fi ìji bo ìbòrí wọn. Àwọn kérúbù kọjú sí ara wọn, wọ́n ń wo ìbòrí náà.
10 Ó se tábìlì igi kaṣíá ìgbọ̀nwọ́ méjì ní gígùn, ìgbọ̀nwọ́ kan ní fífẹ̀, àti ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ní gíga.