18 Aṣọ tita fún ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà jẹ́ ti aṣọ aláró, ti elésèé àlùkò, ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára iṣẹ́ alábẹ́rẹ́ ni. Ó jẹ́ mítà mẹ́sàn-án ní gígùn (9 meters), gẹ́gẹ́ bí aṣọ títa àgbàlá náà, àti gíga rẹ̀ jẹ mítà méjì (2. 3 meters),
19 pẹ̀lú òpó mẹ́rin àti ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ mẹ́rin. Ìkọ́ àti ìgbànú wọn jẹ́ fàdákà, a sì bo orí wọn pẹ̀lú fàdákà.
20 Gbogbo èèkàn àgọ́ tabánákù náà àti ti àyíká àgbàlá náà jẹ́ idẹ.
21 Wọ̀nyí ni iye ohun èlò tí a lò fún tabánákù náà, tabánákù ẹ̀rí, èyí ti a kọ bí òfin Mósè nípa àwọn ọmọ Léfì ní abẹ́ àkóso Itamari ọmọ Árónì àlùfáà.
22 (Bésálélì ọmọ Úrì, ọmọ Húrì, ti ẹ̀yà Júdà, ṣe ohun gbogbo ti Olúwa pàṣẹ fún Mósè;
23 Pẹ̀lú rẹ̀ ni Óhólíábù ọmọ Áhísámákì, ti ẹ̀yà Dánì-alágbẹ̀dẹ́, àti oníṣẹ́ ọnà àti oníṣọ̀nà iṣẹ́ abẹ́rẹ́ ní aṣọ aláró àti elésèé àlùkò àti òdòdó àti ọ̀gbọ̀ dáradára.)
24 Àròpọ̀ iye wúrà lára wúrà ọrẹ tí a lò fún gbogbo iṣẹ́ ibi mímọ́ náà jẹ́ tálẹ́ńtì mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29) àti ẹgbẹ̀rin (730) sékélì gẹ́gẹ́ bí i sékélì ibi mímọ́.