34 ìbòrí awọ àgbò tí a kùn ní pupa, ìbòrí awọ àti ìji àsọ títa;
35 àpótí ẹ̀rí pẹ̀lú àwọn òpó rẹ̀ àti ìbòrí àánú;
36 tábìlì pẹ̀lú gbogbo ohun èlò rẹ̀ àti àkàrà ìfihàn;
37 ọ̀pá fìtílà kìkì wúrà pẹ̀lú ipele fìtílà rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, àti òróró fún títanná rẹ̀;
38 pẹpẹ wúrà àti òróró ìtasórí, tùràrí dídùn, àti aṣọ títa fún ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà.
39 Pẹpẹ idẹ pẹ̀lú idẹ ọlọ, àwọn òpó rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀; agbada pẹ̀lú ẹṣẹ̀ rẹ̀;
40 aṣọ títa ti àgbàlá pẹ̀lú àwọn òpó rẹ̀ àti àgbàlá, àti aṣọ títa fún ẹnu ọ̀nà àgbàlá; ọ̀já àmùrè àti èèkàn àgọ́ fún àgbàlá náà; gbogbo ohun ọ̀ṣọ́ fún àgọ́, àgọ́ àjọ náà;