1 Mósè dáhùn ó sì wí pé; “Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá gbà mí gbọ́ ń kọ́? Tàbí tí wọn kò fi etí sílẹ̀ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ́nu mi, tí wọn sì wí pé, ‘Olúwa kò farahàn ọ́’?”
2 Ní ìgbà náà ni Olúwa sọ fún un pé, “Kí ni ó wà ní ọwọ́ ọ̀ rẹ nnì?”Ó sì dáhùn pé, “ọ̀pá ni”
3 Olúwa sì sọ pé, “Sọ ọ̀pá náà sílẹ̀.”Mósè sì sọ ọ̀pá náà sílẹ̀, lọ́gán ni ọ̀pá náà di ejò, ó sì sá fún un.
4 Nígbà náà ni Ọlọ́run wá sọ fún un pé, “na ọwọ́ rẹ, kí o sì mú un ni ìrù.” Mósè sì na ọwọ́ rẹ̀, ó sì mu ejò náà, ejò náà sì padà di ọ̀pá tí ó wà ni ọwọ́ rẹ̀.
5 Olúwa sì wí pé, “Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí wọn bá à le è gbàgbọ́ pé, Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn: Ọlọ́run Ábúráhámù, Ọlọ́run Ísáákì, àtì Ọlọ́run Jákọ́bù; tí farahàn ọ́.”
6 Ní ìgbà náà ni Olúwa wí pé, “Ti ọwọ́ rẹ bọ ìnú aṣọ ní igbá àyà rẹ̀.” Mósè sì ti ọwọ́ rẹ̀ bọ inú aṣọ ní igbá àyá rẹ̀, ní ìgbá ti ó sì yọ ọ́ jáde, ọwọ́ rẹ̀ ti dẹ́tẹ̀, ó sì ti funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú.