11 Ta òróró sára agbada náà àti ẹsẹ̀ rẹ, kí o sì yà wọ́n sí mímọ́.
12 “Mú Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ, kí o sì wẹ̀ wọ́n pẹ̀lú omi.
13 Nígbà náà wọ Árónì ní aṣọ mímọ́, ta òróró sí i ní orí, kí o sì yà á sí mímọ́, nítorí kí ó lè máa sìn mi bí àlùfáà.
14 Mú àwọn ọmọ rẹ̀ kí o sì fi aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀ wọ́n.
15 Ta òróró sí wọn ní orí gẹ́gẹ́ bí o ti ta òróró sí baba wọn ńi orí, nítorí kì wọn lè máa sìn mi bí àlùfáà. Ìtasórí wọn yóò jẹ́ iṣẹ́ àlùfáà ti yóò máa lò fún gbogbo ìrandíran tó ń bọ̀.”
16 Mósè ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún-un.
17 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé Àgọ́ náà ró ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ìn-ní ní ọdún kejì.